Genesis 22:1-10

Ọlọ́run dán Abrahamu wò

1 aNígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.”

Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

2 bỌlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moriah, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.”

3Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un. 4Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè, 5Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.”

6Abrahamu sì gbé igi ẹbọ sísun náà ru Isaaki, òun fúnrarẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ, 7Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.”

Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.”

Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”

8Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ.

9 cNígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà. 10Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.
Copyright information for YorBMYO